Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mika 4:9-13 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Kí ló dé, tí ò ń pariwo bẹ́ẹ̀? Ṣé ẹ kò ní ọba ni? Tabi ẹ kò ní olùdámọ̀ràn mọ́, ni ìrora fi mu yín bí obinrin tí ń rọbí?

10. Ẹ máa yí nílẹ̀, kí ẹ sì máa kérora bí obinrin tí ń rọbí, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu; nítorí pé ẹ gbọdọ̀ jáde ní ìlú yín wàyí, ẹ óo lọ máa gbé inú pápá; ẹ óo lọ sí Babiloni. Ibẹ̀ ni a óo ti gbà yín là, níbẹ̀ ni OLUWA yóo ti rà yín pada kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.

11. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè dojú ìjà kọ yín nisinsinyii, wọ́n sì ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sọ Sioni di aláìmọ́, kí á sì dójúlé e.”

12. Ṣugbọn àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò mọ èrò OLUWA, ìpinnu rẹ̀ kò sì yé wọn, pé ó ti kó wọn jọ láti pa wọ́n bí ẹni pa ọkà ní ibi ìpakà.

13. Ẹ dìde kí ẹ tẹ àwọn ọ̀tá yín mọ́lẹ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Nítorí n óo mú kí ìwo rẹ lágbára bí irin, pátákò ẹsẹ̀ rẹ yóo sì dàbí idẹ; o óo fọ́ ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè túútúú, o óo sì ya ọrọ̀ wọn sọ́tọ̀ fún OLUWA, nǹkan ìní wọn yóo jẹ́ ti OLUWA àgbáyé.

Ka pipe ipin Mika 4