Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mika 3:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu, ati ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli! Ṣé kò yẹ kí ẹ mọ̀ nípa ìdájọ́ òtítọ́?

2. Ẹ̀yin tí ẹ kórìíra ohun rere, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi, ẹ̀yin tí ẹ bó awọ lára àwọn eniyan mi, tí ẹ sì ya ẹran ara egungun wọn;

3. ẹ̀yin ni ẹ jẹ ẹran ara àwọn eniyan mi, ẹ bó awọ kúrò lára wọn, ẹ sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́, ẹ gé wọn lékìrí lékìrí bí ẹran inú ìsaasùn, àní, bí ẹran inú ìkòkò.

4. Nígbà tí ó bá yá, wọn yóo ké pe OLUWA, ṣugbọn kò ní dá wọn lóhùn; yóo fi ojú pamọ́ fún wọn, nítorí nǹkan burúkú tí wọ́n ṣe.

Ka pipe ipin Mika 3