Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mika 1:11-16 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Ṣafiri ẹ máa rìn ní ìhòòhò pẹlu ìtìjú lọ sí ìgbèkùn. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Saanani, ẹ má jáde kúrò níbẹ̀, nítorí ẹkún àwọn ará Beteseli, yóo fihàn yín pé kò sí ààbò yín lọ́dọ̀ wọn.

12. Àwọn ará Marotu ń retí ire pẹlu gbogbo ọkàn wọn, nítorí pé ibi ti dé sí bodè Jerusalẹmu láti ọ̀dọ̀ OLUWA.

13. Ẹ̀yin ará Lakiṣi, ẹ de kẹ̀kẹ́ ogun yín mọ́ ẹṣin; ọ̀dọ̀ yín ni ẹ̀ṣẹ̀ ti kọ́ bẹ̀rẹ̀, tí ó sì tàn lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Jerusalẹmu, nítorí pé nípasẹ̀ yín ni Israẹli ṣe dẹ́ṣẹ̀.

14. Nítorí náà, ẹ óo fún àwọn ará Moreṣeti Gati ní ẹ̀bùn ìdágbére; ilé Akisibu yóo sì jẹ́ ohun ìtànjẹ fún àwọn ọba Israẹli.

15. Ẹ̀yin ará Mareṣa, n óo tún jẹ́ kí àwọn ọ̀tá borí yín; ògo Israẹli yóo sì lọ sí ọ̀dọ̀ Adulamu.

16. Ẹ̀yin ará Juda, ẹ fá irun orí yín láti ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ yín tí ẹ fẹ́ràn; kí orí yín pá bí orí igún, nítorí a óo kó àwọn ọmọ yín ní ìgbèkùn kúrò lọ́dọ̀ yín.

Ka pipe ipin Mika 1