Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 9:19-24 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ó mú ọ̀rá akọ mààlúù, ati ti àgbò náà, pẹlu ìrù wọn tí ó lọ́ràá, ati ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú wọn, ati kíndìnrín ati ẹ̀dọ̀ wọn.

20. Ó kó gbogbo ọ̀rá náà lé orí igẹ̀ ẹran náà; ó sun ún lórí pẹpẹ.

21. Ṣugbọn ó mú àwọn igẹ̀ ẹran náà ati itan ọ̀tún wọn, ó fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, bí Mose ti pa á láṣẹ.

22. Lẹ́yìn náà, Aaroni kọjú sí àwọn eniyan náà, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn náà, ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi tí ó ti ń rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia.

23. Mose ati Aaroni bá wọ inú Àgọ́ Àjọ lọ. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn eniyan náà, ògo OLUWA sì yọ sí gbogbo wọn.

24. Lójijì, iná ṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ó jó ẹbọ sísun náà, ati ọ̀rá tí ó wà lórí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan rí i, wọ́n kígbe sókè, wọ́n sì dojúbolẹ̀.

Ka pipe ipin Lefitiku 9