Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 8:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose pé,

2. “Mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati ẹ̀wù iṣẹ́ alufaa wọn, ati òróró ìyàsímímọ́, ati akọ mààlúù fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò meji náà, ati agbọ̀n burẹdi tí kò ní ìwúkàrà.

3. Lẹ́yìn náà, kó gbogbo àwọn eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.”

4. Mose bá pe gbogbo ìjọ eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

5. Ó sọ fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA pàṣẹ pé ẹ gbọdọ̀ ṣe nìyí.”

Ka pipe ipin Lefitiku 8