Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 6:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose, pé,

2. “Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nípa ṣíṣe èyíkéyìí ninu nǹkan wọnyi: kì báà jẹ́ pé ó kọ̀ láti dá ohun tí aládùúgbò rẹ̀ fi dógò pada ni, tabi pé ó ja aládùúgbò rẹ̀ lólè ni, tabi pé ó rẹ́ ẹ jẹ ni,

3. tabi pé ó rí nǹkan rẹ̀ tí ó sọnù he, tí ó sì ṣe bí ẹni pé òun kò rí i, tabi tí ó búra èké nípa ohunkohun, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó dá.

4. Bí ẹnikẹ́ni bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí, kí ó dá ohun tí ó jí pada, tabi ohun tí ó fi ìrẹ́jẹ gbà, tabi ohun tí wọ́n fi dógò lọ́dọ̀ rẹ̀, tabi ohun tí ó sọnù tí ó rí he,

5. tabi ohunkohun tí ó ti búra èké sí. Kí ó san án pé pérépéré kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, nígbà tí ó bá dá ohun náà pada fún olúwarẹ̀, ní ọjọ́ tí yóo bá rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

6. Kí ó mú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi tọ alufaa wá, ohun ìrúbọ náà ni àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n, kí ó rí i pé àgbò náà tó iye tí eniyan lè ra ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

7. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún ẹni náà níwájú OLUWA, OLUWA yóo sì dárí ohunkohun tí ó bá ṣe jì í.”

8. OLUWA sọ fún Mose pé,

9. “Pa á láṣẹ fún Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ti ẹbọ sísun: ẹbọ sísun níláti wà lórí ààrò lórí pẹpẹ ní gbogbo òru títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iná sì níláti máa jò lórí pẹpẹ náà ní gbogbo ìgbà.

10. Kí alufaa wọ ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ funfun rẹ̀, ati ṣòkòtò aṣọ funfun, kí ó kó eérú ẹbọ tí ó ti fi iná sun kúrò lórí pẹpẹ, kí ó sì dà á sí ibìkan.

11. Lẹ́yìn náà, kí ó bọ́ aṣọ iṣẹ́ alufaa rẹ̀ kí ó sì wọ aṣọ mìíràn, kí ó wá ru eérú náà jáde kúrò ninu àgọ́ sí ibi mímọ́ kan.

12. Kí iná orí pẹpẹ náà sì máa jó, kò gbọdọ̀ kú nígbà kan. Kí alufaa máa kó igi sí i ní àràárọ̀; kí ó máa to ẹbọ sísun lé e lórí, orí rẹ̀ ni yóo sì ti máa sun ọ̀rá ẹran tí ó bá fi rú ẹbọ alaafia.

13. Iná orí pẹpẹ náà gbọdọ̀ máa jó nígbà gbogbo, kò gbọdọ̀ kú.

Ka pipe ipin Lefitiku 6