Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 5:14-19 BIBELI MIMỌ (BM)

14. OLUWA sọ fún Mose pé:

15. “Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀ nípa pé kò san àwọn nǹkan tíí ṣe ti OLUWA fún OLUWA, ohun tí yóo mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi fún OLUWA ni: àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n, láti inú agbo aguntan rẹ̀, ìwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn fadaka ninu ilé OLUWA ni wọn yóo lò láti fi díyelé àgbò náà; ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ni.

16. Yóo san ohun tí ó yẹ kí ó san fún OLUWA tí kò san, pẹlu èlé ìdámárùn-ún rẹ̀ fún alufaa, alufaa yóo sì fi àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe ètùtù fún un, a óo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í.

17. “Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣe ọ̀kan ninu àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ̀, sibẹ ó jẹ̀bi, yóo sì san ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

18. Kí ó mú àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n wá sí ọ̀dọ̀ alufaa, ó gbọdọ̀ rí i pé àgbò yìí tó iye tí wọn ń ra ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, alufaa yóo ṣe ètùtù fún un fún àṣìṣe rẹ̀ tí ó ṣèèṣì ṣe, OLUWA yóo sì dáríjì í.

19. Ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá sí OLUWA ni.”

Ka pipe ipin Lefitiku 5