Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 3:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Bí ẹnìkan bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia, tí ó sì mú ẹran láti inú agbo ẹran rẹ̀ fún ẹbọ náà, kì báà jẹ́ akọ tabi abo, ó níláti jẹ́ èyí tí kò ní àbààwọ́n níwájú OLUWA.

2. Kí ó gbé ọwọ́ lé orí ẹran náà, kí ó sì pa á lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Kí àwọn alufaa ọmọ Aaroni da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára pẹpẹ náà yípo.

3. Kí ó mú àwọn nǹkan wọnyi ninu ẹbọ alaafia náà, kí ó fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA: ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀ ati ọ̀rá tí ó wà lára ìfun rẹ̀,

4. ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n. Nígbà tí ó bá ń yọ kíndìnrín rẹ̀, yóo yọ ẹ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́ ọn láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA.

5. Àwọn ọmọ Aaroni yóo sun wọ́n lórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ; ẹbọ sísun ni, tí ó ní òórùn dídùn, tí inú OLUWA sì dùn sí.

6. “Bí ó bá jẹ́ pé aguntan tabi ewúrẹ́ ni yóo mú láti inú agbo ẹran rẹ̀ láti fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, kì báà jẹ́ akọ tabi abo ẹran, ó gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí kò ní àbààwọ́n.

7. Bí ó bá jẹ́ ọ̀dọ́ aguntan ni yóo fi rúbọ, kí ó mú un wá siwaju OLUWA,

8. kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú Àgọ́ Àjọ náà; kí àwọn ọmọ Aaroni da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà yípo.

Ka pipe ipin Lefitiku 3