Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 26:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe oriṣa-koriṣa kan fún ara yín, tabi kí ẹ gbé ère gbígbẹ́ kalẹ̀, tabi kí ẹ ri ọ̀wọ̀n òkúta gbígbẹ́ mọ́lẹ̀, kí ẹ sì máa bọ wọ́n, ní gbogbo ilẹ̀ yín, nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

2. Ẹ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi. Èmi ni OLUWA.

3. “Bí ẹ bá ń tẹ̀lé ìlànà mi, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin mi mọ́,

4. n óo mú kí òjò rọ̀ ní àkókò rẹ̀, ilẹ̀ yóo mú ìbísí rẹ̀ wá, àwọn igi inú oko yóo sì máa so èso.

5. Ẹ óo máa pa ọkà títí tí èso àjàrà yóo fi tó ká, ẹ óo sì máa ká èso àjàrà lọ́wọ́, títí àwọn nǹkan oko yóo fi tó gbìn. Ẹ óo jẹ, ẹ óo yó, ẹ óo sì máa gbé inú ilẹ̀ yín láìléwu.

6. “N óo fun yín ní alaafia ní ilẹ̀ náà, ẹ óo dùbúlẹ̀, kò sí ẹnìkan tí yóo sì dẹ́rùbà yín. N óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, ogun kò sì ní jà ní ilẹ̀ náà.

7. Ẹ óo lé àwọn ọ̀tá yín jáde, ẹ óo sì máa fi idà pa wọ́n.

8. Marun-un ninu yín yóo lé ọgọrun-un ọ̀tá sẹ́yìn, ọgọrun-un ninu yín yóo sì lé ẹgbaarun (10,000) àwọn ọ̀tá yín sẹ́yìn, idà ni ẹ óo fi máa pa wọ́n.

9. N óo fi ojurere wò yín, n óo mú kí ẹ máa bímọlémọ, kí ẹ sì pọ̀ sí i, n óo sì fi ìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu yín.

10. Ẹ óo jẹ àwọn nǹkan oko tí ẹ kó sí inú abà fún ọjọ́ pípẹ́, ẹ óo sì máa ru ìyókù wọn dànù kí ẹ lè rí ààyè kó tuntun sí.

Ka pipe ipin Lefitiku 26