Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 24:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose pé,

2. “Pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli pé kí wọn mú ojúlówó òróró olifi wá fún àtùpà ilé mímọ́ mi, kí ó lè máa wà ní títàn nígbà gbogbo.

3. Ní ìrọ̀lẹ́, Aaroni yóo máa tan àtùpà náà kalẹ̀ níwájú aṣọ ìbòjú tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí, wọn yóo máa wà ní títàn níwájú OLUWA títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Èyí yóo wà bí ìlànà, títí lae, fún arọmọdọmọ yín.

4. Aaroni yóo sì máa ṣe ìtọ́jú àwọn àtùpà tí wọ́n wà lórí ọ̀pá fìtílà wúrà, kí wọ́n lè máa wà ní títàn níwájú OLUWA nígbà gbogbo.

5. “Ẹ mú ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, kí ẹ sì fi ṣe burẹdi mejila, ìdámárùn-ún ìwọ̀n ìyẹ̀fun efa kan ni kí ẹ fi ṣe burẹdi kọ̀ọ̀kan.

6. Ẹ sì máa tò wọ́n kalẹ̀ sí ọ̀nà meji; mẹfa mẹfa ní ọ̀nà kọ̀ọ̀kan, lórí tabili tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe.

7. Ẹ fi ojúlówó turari sí ọ̀nà kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n lè fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí àmì fún ìrántí.

8. Ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi, Aaroni yóo máa tò wọ́n kalẹ̀ níwájú OLUWA nígbà gbogbo, ní orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu títí lae.

Ka pipe ipin Lefitiku 24