Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 22:4-6 BIBELI MIMỌ (BM)

4. “Ẹnikẹ́ni ninu ìran Aaroni tí ó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí ara rẹ̀ bá ń tú, kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà, títí tí yóo fi di mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́, kì báà jẹ́ pé ó fara kan òkú ni, tabi pé ó fara kan ẹni tí nǹkan ọkunrin jáde lára rẹ̀,

5. tabi ẹni tí ó bá fara kan èyíkéyìí ninu àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń káàkiri, èyí tí ó lè sọ eniyan di aláìmọ́, tabi ẹnikẹ́ni tí ó lè kó àìmọ́ bá eniyan, ohun yòówù tí àìmọ́ rẹ̀ lè jẹ́.

6. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tabi irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; kò sì ní jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà títí tí yóo fi wẹ̀.

Ka pipe ipin Lefitiku 22