Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 18:16-25 BIBELI MIMỌ (BM)

16. O kò gbọdọ̀ bá aya arakunrin rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ohun ìtìjú ni, ìhòòhò arakunrin rẹ ni.

17. O kò gbọdọ̀ bá obinrin kan lòpọ̀ tán, kí o tún bá ọmọ rẹ̀ obinrin lòpọ̀ tabi ọmọ ọmọ rẹ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkunrin tabi ọmọ ọmọ rẹ̀ obinrin, nítorí pé, ẹbí rẹ̀ ni wọ́n jẹ́, ìwà burúkú ni èyí jẹ́.

18. O kò gbọdọ̀ fi ọmọ ìyá, tabi ọmọ baba iyawo rẹ ṣe aya níwọ̀n ìgbà tí aya rẹ tí í ṣe ẹ̀gbọ́n rẹ̀ bá wà láàyè.

19. “O kò gbọdọ̀ bá obinrin lòpọ̀, nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́.

20. O kò gbọdọ̀ bá aya aládùúgbò rẹ lòpọ̀, kí o sì sọ ara rẹ di aláìmọ́ pẹlu rẹ̀.

21. O kò gbọdọ̀ fa èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ kalẹ̀ fún lílò níbi ìbọ̀rìṣà Moleki, kí o sì ti ipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọrun rẹ jẹ́. Èmi ni OLUWA.

22. O kò gbọdọ̀ bá ọkunrin lòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí obinrin, ohun ìríra ni.

23. O kò sì gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni obinrin kò sì gbọdọ̀ fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀; ìwà burúkú ni.

24. “Má ṣe fi èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan tí a dárúkọ wọnyi ba ara rẹ jẹ́, nítorí pé, nǹkan wọnyi ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mò ń lé jáde kúrò níwájú yín fi ba ara wọn jẹ́.

25. Ilẹ̀ náà di ìbàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ ẹ́, ilẹ̀ náà sì ń ti àwọn eniyan inú rẹ̀ jáde.

Ka pipe ipin Lefitiku 18