Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 15:23-31 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Kì báà jẹ́ ibùsùn rẹ̀ ni, tabi ohunkohun tí ó fi jókòó ni eniyan bá fi ara kàn, ẹni náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

24. Bí ọkunrin kan bá bá a lòpọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, ọkunrin náà yóo jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ meje, ibùsùn tí ọkunrin náà bá sì dùbúlẹ̀ lé lórí yóo jẹ́ aláìmọ́.

25. “Bí ẹ̀jẹ̀ bá ń dà lára obinrin fún ọpọlọpọ ọjọ́, tí kì í sì í ṣe àkókò nǹkan oṣù rẹ̀, tabi tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá dà kọjá iye ọjọ́ tí ó yẹ kí ó dà, ó jẹ́ aláìmọ́ ní gbogbo àkókò tí ẹ̀jẹ̀ ń dà lára rẹ̀. Yóo jẹ́ aláìmọ́ bí ìgbà tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀.

26. Ibùsùn tí ó bá dùbúlẹ̀ lé lórí, ní gbogbo ọjọ́ tí nǹkan yìí bá fi ń dà lára rẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́; ohunkohun tí ó bá sì fi jókòó di aláìmọ́ gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀.

27. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ara kan ibùsùn tabi ìjókòó rẹ̀, yóo di aláìmọ́; kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

28. Ṣugbọn nígbà tí ẹ̀jẹ̀ náà bá dá, kí ó ka ọjọ́ meje lẹ́yìn ọjọ́ náà; lẹ́yìn náà, ó di mímọ́.

29. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, kí ó mú àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji tọ alufaa lọ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

30. Kí alufaa fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, kí ó sì fi ekeji rú ẹbọ sísun, kí ó ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA nítorí ohun àìmọ́ tí ó jáde lára rẹ̀.

31. “Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe ya àwọn eniyan Israẹli kúrò lára àìmọ́ wọn, kí wọ́n má baà sọ ibi mímọ́ tí ó wà láàrin wọn di aláìmọ́, kí wọ́n sì kú.”

Ka pipe ipin Lefitiku 15