Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 14:21-31 BIBELI MIMỌ (BM)

21. “Ṣugbọn bí adẹ́tẹ̀ náà bá talaka tóbẹ́ẹ̀ tí apá rẹ̀ kò ká àwọn nǹkan tí a kà sílẹ̀ wọnyi, ó lè mú àgbò kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, tí alufaa yóo fì, láti fi ṣe ètùtù fún un. Kí ó sì tún mú ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun kan tí ó kúnná dáradára, tí wọ́n fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ, pẹlu ìwọ̀n ìgò òróró kan,

22. ati àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, èyíkéyìí tí apá rẹ̀ bá ká. Wọn yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, wọn yóo sì fi ekeji rú ẹbọ sísun.

23. Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo kó wọn tọ alufaa wá ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, níwájú OLUWA fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀.

24. Alufaa yóo mú àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ati ìwọ̀n ìgò òróró náà, yóo fì wọ́n bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.

25. Yóo pa àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, yóo sì mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́ ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

26. Alufaa yóo bu díẹ̀ ninu òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀,

27. yóo ti ìka bọ inú òróró tí ó wà ní ọwọ́ òsì yìí, yóo sì wọ́n ọn sílẹ̀ níwájú OLUWA nígbà meje.

28. Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu òróró tí ó wà ni ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́ ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ tí ó ti kọ́ fi ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi kàn.

29. Alufaa yóo mú òróró tí ó kù ní ọwọ́ rẹ̀ yóo sì fi ra orí ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́, láti fi ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA.

30. Yóo fi èyí tí apá rẹ̀ bá ká rúbọ: yálà àdàbà tabi ẹyẹlé;

31. ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ. Alufaa yóo sì ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA.

Ka pipe ipin Lefitiku 14