Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 9:2-6 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ pada dé sórí ilẹ̀ wọn, ní ìlú wọn, ni àwọn ọmọ Israẹli, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn òṣìṣẹ́ inú tẹmpili.

3. Àwọn eniyan tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Juda, Bẹnjamini, Efuraimu, ati Manase tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí:

4. Utai ọmọ Amihudu, ọmọ Omiri, ọmọ Imiri, ọmọ Bani, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Pẹrẹsi, ọmọ Juda.

5. Àwọn ọmọ Ṣilo ni Asaaya, àkọ́bí rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀.

6. Àwọn ọmọ ti Sera ni Jeueli ati àwọn ìbátan rẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó dín mẹ́wàá (690).

Ka pipe ipin Kronika Kinni 9