Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 9:18-27 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Wọ́n ń ṣọ́ apá ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn ilé ọba. Àwọn ni wọ́n ń ṣọ́ àgọ́ àwọn ọmọ Lefi tẹ́lẹ̀.

19. Ṣalumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora ati àwọn ará ilé baba rẹ̀. Gbogbo ìdílé Kora ni alabojuto iṣẹ́ ìsìn ninu tẹmpili ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé àgọ́, gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti jẹ́ alabojuto Àgọ́ OLUWA ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀.

20. Finehasi, ọmọ Eleasari ni olórí wọn tẹ́lẹ̀ rí, OLUWA sì wà pẹlu rẹ̀.

21. Sakaraya, ọmọ Meṣelemaya ni olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

22. Gbogbo àwọn olùṣọ́nà tí wọ́n yàn láti máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé jẹ́ igba ó lé mejila (212). A kọ orúkọ wọn sinu ìwé gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní agbègbè wọn. Dafidi ati Samuẹli aríran, ni wọ́n fi wọ́n sí ipò pataki náà.

23. Nítorí náà, àwọn ati àwọn ọmọ wọn ni wọ́n ń ṣe alabojuto ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, àwọn ni wọ́n fi ṣe olùṣọ́ Àgọ́ Àjọ.

24. Ọ̀gá aṣọ́nà kọ̀ọ̀kan wà ní ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin: ní ìhà ìlà oòrùn, ati ìwọ̀ oòrùn, ati àríwá, ati gúsù;

25. àwọn eniyan wọn tí wọn ń gbé àwọn ìletò a máa wá ní ọjọ́ meje meje, láti ìgbà dé ìgbà, láti wà pẹlu àwọn olórí ọ̀gá aṣọ́nà mẹrin náà.

26. Nítorí àwọn olórí mẹrin wọnyi, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, ni wọ́n tún ń ṣe alabojuto àwọn yàrá tẹmpili ati àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé Ọlọrun.

27. Wọ́n ń gbé àyíká ilé Ọlọrun, nítorí iṣẹ́ wọn ni láti máa bojútó o, ati láti máa ṣí ìlẹ̀kùn rẹ̀ ní àràárọ̀.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 9