Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 9:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. A kọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìran wọn; a kọ wọ́n sinu ìwé Àwọn Ọba Israẹli.A kó àwọn ẹ̀yà Juda ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni nítorí pé wọ́n ṣe alaiṣootọ sí Ọlọrun.

2. Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ pada dé sórí ilẹ̀ wọn, ní ìlú wọn, ni àwọn ọmọ Israẹli, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn òṣìṣẹ́ inú tẹmpili.

3. Àwọn eniyan tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Juda, Bẹnjamini, Efuraimu, ati Manase tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí:

4. Utai ọmọ Amihudu, ọmọ Omiri, ọmọ Imiri, ọmọ Bani, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Pẹrẹsi, ọmọ Juda.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 9