Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 8:9-22 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ọmọ meje ni Hodeṣi bí fún un: Jobabu, Sibia, Meṣa, ati Malikami,

10. Jeusi, Sakia ati Mirima. Gbogbo wọn jẹ́ baálé baálé ní ìdílé wọn.

11. Huṣimu náà bí ọmọkunrin meji fún un: Abitubu ati Elipaali.

12. Elipaali bí ọmọkunrin mẹta: Eberi, Miṣamu ati Ṣemedi. Ṣemedi yìí ni ó kọ́ àwọn ìlú Ono, Lodi, ati gbogbo àwọn ìletò tí ó yí wọn ká.

13. Beraya ati Ṣema ni olórí àwọn ìdílé tí wọn ń gbé ìlú Aijaloni, àwọn sì ni wọ́n lé àwọn tí wọn ń gbé ìlú Gati tẹ́lẹ̀ kúrò;

14. àwọn ọmọ Beraya ni: Ahio, Ṣaṣaki, ati Jeremotu,

15. Sebadaya, Aradi, ati Ederi,

16. Mikaeli, Iṣipa ati Joha.

17. Àwọn ọmọ Elipaali ni: Sebadaya, Meṣulamu, Hiṣiki, ati Heberi,

18. Iṣimerai, Isilaya ati Jobabu.

19. Àwọn ọmọ Ṣimei ni: Jakimu, Sikiri, ati Sabidi;

20. Elienai, Siletai, ati Elieli;

21. Adaaya, Beraaya ati Ṣimirati;

22. Àwọn ọmọ Ṣaṣaki nìwọ̀nyí: Iṣipani, Eberi, ati Elieli;

Ka pipe ipin Kronika Kinni 8