Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 7:24-29 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Efuraimu ní ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣeera, òun ló kọ́ ìlú Beti Horoni ti òkè ati ti ìsàlẹ̀, ati Useni Ṣeera.

25. Orúkọ àwọn ọmọ ati arọmọdọmọ Efuraimu yòókù ni Refa, baba Reṣefu, baba Tela, baba Tahani;

26. baba Ladani, baba Amihudu, baba Eliṣama;

27. baba Nuni, baba Joṣua.

28. Àwọn ilẹ̀ ìní wọn ati àwọn agbègbè tí wọ́n tẹ̀dó sí nìwọ̀nyí: Bẹtẹli, Naarani ní apá ìlà oòrùn, Geseri ní apá ìwọ̀ oòrùn, Ṣekemu ati Aya; pẹlu àwọn ìletò tí ó wà lẹ́bàá àyíká wọn.

29. Àwọn ìlú wọnyi wà lẹ́bàá ààlà ilẹ̀ àwọn ará Manase: Beti Ṣani, Taanaki, Megido, Dori ati gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká.Níbẹ̀ ni àwọn ìran Josẹfu, ọmọ Jakọbu ń gbé.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 7