Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 7:17-22 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ulamu sì bí Bedani. Àwọn ni ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase.

18. Arabinrin Gileadi kan tí ń jẹ́ Hamoleketu ni ó bí Iṣodu, Abieseri, ati Mahila.

19. Ṣemida bí ọmọkunrin mẹrin: Ahiani, Ṣekemu, Liki, ati Aniamu.

20. Àwọn arọmọdọmọ Efuraimu nìwọ̀nyí: Ṣutela ni baba Beredi, baba Tahati, baba Eleada, baba Tahati,

21. baba Sabadi, baba Ṣutela, Eseri, ati Eleadi; Eseri ati Eleadi yìí ni àwọn ará ìlú Gati pa nígbà tí wọ́n lọ kó ẹran ọ̀sìn àwọn ará Gati.

22. Baba wọn, Efuraimu, ṣọ̀fọ̀ wọn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Àwọn arakunrin rẹ̀ bá wá láti tù ú ninu.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 7