Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 6:74-81 BIBELI MIMỌ (BM)

74. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, wọ́n fún wọn ní Maṣali ati Abidoni;

75. Hukoku ati Rehobu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.

76. Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Nafutali, wọ́n fún wọn ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Galili, Hamoni, ati Kiriataimu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.

77. Wọ́n pín àwọn ìlú wọnyi fún àwọn ìdílé tí ó kù ninu àwọn ọmọ Merari.Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni, wọ́n fún wọn ní Rimono ati Tabori, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.

78. Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Reubẹni tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní ìkọjá Jọdani níwájú Jẹriko, wọ́n fún wọn ní Beseri tí ó wà ní ara òkè, ati Jahasa,

79. Kedemotu ati Mefaati pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.

80. Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi, wọ́n fún wọn ní Ramoti ní ilẹ̀ Gileadi ati Mahanaimu,

81. Heṣiboni ati Jaseri, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 6