Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 6:4-12 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ìran Eleasari ati àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ nìwọ̀nyí: Eleasari ni baba Finehasi, Finehasi ni ó bí Abiṣua;

5. Abiṣua bí Buki, Buki sì bí Usi.

6. Usi ni baba Serahaya, Serahaya ló bí Meraiotu,

7. Meraiotu bí Amaraya, Amaraya sì bí Ahitubu.

8. Ahitubu ni baba Sadoku, Sadoku bí Ahimaasi,

9. Ahimaasi bí Asaraya, Asaraya sì bí Johanani.

10. Johanani bí Asaraya (òun ni alufaa tí ó wà ninu tẹmpili tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).

11. Asaraya ni baba Amaraya, Amaraya ni ó bí Ahitubu;

12. Ahitubu bí Sadoku, Sadoku sì bí Ṣalumu.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 6