Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 6:39-49 BIBELI MIMỌ (BM)

39. Asafu, arakunrin rẹ̀, ni olórí àwọn ẹgbẹ́ akọrin tí ń dúró ní apá ọ̀tun rẹ̀. Asafu yìí jẹ́ ọmọ Berekaya, ọmọ Ṣimea;

40. Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseaya, ọmọ Malikija,

41. ọmọ Etini, ọmọ Sera, ọmọ Adaya;

42. ọmọ Etani, ọmọ Sima, ọmọ Ṣimei,

43. ọmọ Jahati, ọmọ Geriṣomu, ọmọ Lefi.

44. Etani arakunrin wọn láti inú ìdílé Merari ni olórí àwọn ẹgbẹ́ akọrin tí ń dúró ní apá òsì rẹ̀. Ìran Etani títí lọ kan Lefi nìyí: ọmọ Kiṣi ni Etani, ọmọ Abidi, ọmọ Maluki;

45. ọmọ Haṣabaya, ọmọ Amasaya, ọmọ Hilikaya;

46. ọmọ Amisi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣemeri;

47. ọmọ Mahili, ọmọ Muṣi, ọmọ Merari, ọmọ Lefi.

48. Wọ́n yan àwọn ọmọ Lefi, arakunrin wọn yòókù láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó kù ninu ilé Ọlọrun.

49. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n máa ń rúbọ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun ati lórí pẹpẹ turari; àwọn ni wọ́n máa ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ìsìn ninu ibi mímọ́ jùlọ, tí wọ́n sì máa ń ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose, iranṣẹ Ọlọrun là sílẹ̀.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 6