Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 6:26-41 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Àwọn ọmọ Ahimotu nìwọ̀nyí: Elikana ni baba Sofai, Sofai ni ó bí Nahati;

27. Nahati bí Eliabu, Eliabu bí Jerohamu, Jerohamu sì bí Elikana.

28. Samuẹli bí ọmọkunrin meji: Joẹli ni àkọ́bí, Abija sì ni ikeji.

29. Àwọn ọmọ Merari nìwọ̀nyí: Mahili ni baba Libini, Libini bí Ṣimei,

30. Ṣimei bí Usali, Usali bí Ṣimea, Ṣimea bí Hagaya, Hagaya sì bí Asaya.

31. Dafidi fi àwọn wọnyi ṣe alákòóso ẹgbẹ́ akọrin ninu ilé OLUWA lẹ́yìn tí wọn ti gbé Àpótí Majẹmu OLUWA sibẹ;

32. àwọn ni wọ́n ń kọ orin ninu Àgọ́ Àjọ títí tí Solomoni fi kọ́ ilé OLUWA parí ní Jerusalẹmu; àṣegbà ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ wọn.

33. Àwọn tí wọ́n ṣiṣẹ́ náà, pẹlu àwọn ọmọ wọn nìwọ̀nyí:Ninu ìdílé Kohati: Hemani, akọrin, ọmọ Joẹli, ọmọ Samuẹli,

34. ọmọ Elikana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toa,

35. ọmọ Sufu, ọmọ Elikana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,

36. ọmọ Elikana, ọmọ Joẹli, ọmọ Asaraya, ọmọ Sefanaya,

37. ọmọ Tahati, ọmọ Asiri, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora,

38. ọmọ Iṣari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli.

39. Asafu, arakunrin rẹ̀, ni olórí àwọn ẹgbẹ́ akọrin tí ń dúró ní apá ọ̀tun rẹ̀. Asafu yìí jẹ́ ọmọ Berekaya, ọmọ Ṣimea;

40. Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseaya, ọmọ Malikija,

41. ọmọ Etini, ọmọ Sera, ọmọ Adaya;

Ka pipe ipin Kronika Kinni 6