Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 6:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: Geṣomu, Kohati ati Merari.

2. Kohati bí ọmọkunrin mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli.

3. Amramu bí ọmọ mẹta: Aaroni, Mose, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Miriamu.Aaroni bí ọmọkunrin mẹrin: Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari.

4. Ìran Eleasari ati àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ nìwọ̀nyí: Eleasari ni baba Finehasi, Finehasi ni ó bí Abiṣua;

5. Abiṣua bí Buki, Buki sì bí Usi.

6. Usi ni baba Serahaya, Serahaya ló bí Meraiotu,

7. Meraiotu bí Amaraya, Amaraya sì bí Ahitubu.

8. Ahitubu ni baba Sadoku, Sadoku bí Ahimaasi,

9. Ahimaasi bí Asaraya, Asaraya sì bí Johanani.

10. Johanani bí Asaraya (òun ni alufaa tí ó wà ninu tẹmpili tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).

Ka pipe ipin Kronika Kinni 6