Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 4:9-15 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ọkunrin kan, tí à ń pè ní Jabesi, jẹ́ eniyan pataki ju àwọn arakunrin rẹ̀ lọ. Ìyá rẹ̀ sọ ọ́ ní orúkọ yìí nítorí ìrora pupọ tí ó ní nígbà tí ó bí i.

10. Jabesi gbadura sí Ọlọrun Israẹli pé, “Ọlọrun jọ̀wọ́ bukun mi, sì jẹ́ kí ilẹ̀ ìní mi pọ̀ sí i. Wà pẹlu mi, pa mí mọ́ kúrò ninu ewu, má jẹ́ kí jamba ṣe mí!” Ọlọrun sì ṣe ohun tí ó fẹ́ fún un.

11. Kelubu, arakunrin Ṣuha, ni baba Mehiri, Mehiri ni baba Eṣitoni.

12. Eṣitoni yìí ni ó bí Betirafa, Pasea ati Tẹhina. Tẹhina sì ni baba Irinahaṣi. Àwọn ni wọ́n ń gbé Reka.

13. Kenasi bí ọmọ meji: Otinieli ati Seraaya. Otinieli náà bí Hatati ati Meonotai.

14. Meonotai ni baba Ofira.Seraaya sì ni baba Joabu, baba àwọn ará Geharaṣimu, ìlú àwọn oníṣọ̀nà. Àwọn ni wọ́n tẹ gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ dó.

15. Kalebu, ọmọ Jefune, bí ọmọ mẹta: Iru, Ela, ati Naamu. Ela ni ó bí Kenasi.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 4