Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 4:35-43 BIBELI MIMỌ (BM)

35. Joẹli, ati Jehu, ọmọ Joṣibaya, ọmọ Seraaya, ọmọ Asieli.

36. Elioenai, Jaakoba, ati Jeṣohaya; Asaya, Adieli, Jesimieli ati Bẹnaya;

37. Sisa, ọmọ Ṣifi, ọmọ Aloni, ọmọ Jedaaya, ọmọ Ṣimiri, ọmọ Ṣemaaya.

38. Gbogbo wọn jẹ́ olórí ní ìdílé wọn, ìdílé àwọn baba wọn sì pọ̀ lọpọlọpọ.

39. Wọ́n rìn títí dé ẹnubodè Gedori, ní apá ìlà oòrùn àfonífojì, láti wá koríko fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.

40. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí ilẹ̀ tí ó ní koríko, tí ó sì dára fún àwọn ẹran wọn. Ilẹ̀ náà tẹ́jú, ó parọ́rọ́, alaafia sì wà níbẹ̀; àwọn ọmọ Hamu ni wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí.

41. Nígbà tí Hesekaya, ọba Juda wà lórí oyè, àwọn tí a ti dárúkọ wọnyi lọ sí Meuni, wọ́n ba àgọ́ àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ jẹ́, wọ́n pa wọ́n run títí di òní, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilẹ̀ tiwọn, nítorí pé koríko tútù pọ̀ níbẹ̀ fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.

42. Ẹẹdẹgbẹta (500) ninu àwọn eniyan Simeoni ló lọ sí òkè Seiri; àwọn olórí wọn ni: Pelataya, Nearaya, Refaaya, ati Usieli, lára àwọn ọmọ Iṣi.

43. Wọ́n pa àwọn ọmọ Amaleki yòókù tí wọ́n sá àsálà, wọ́n sì ń gbé orí ilẹ̀ wọn títí di òní olónìí.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 4