Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 4:15-27 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Kalebu, ọmọ Jefune, bí ọmọ mẹta: Iru, Ela, ati Naamu. Ela ni ó bí Kenasi.

16. Jehaleli sì ni baba Sifi, Sifa, Tiria, ati Asareli.

17. Ẹsira bí Jeteri, Meredi, Eferi, ati Jaloni. Meredi fẹ́ Bitia, ọmọbinrin Farao. Wọ́n bí ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Miriamu ati ọmọkunrin meji: Ṣamai ati Iṣiba.

18. Iṣiba ni baba Eṣitemoa. Meredi tún ní iyawo mìíràn, òun jẹ́ ará Juda, ó bí ọmọkunrin mẹta fún un: Jeredi, baba Gedori, Heberi baba Soko, ati Jekutieli, baba Sanoa.

19. Hodia fẹ́ arabinrin Nahamu, àwọn ọmọ wọn ni wọ́n ṣẹ ẹ̀yà Garimi, tí wọn ń gbé ìlú Keila sílẹ̀, ati àwọn ìran Maakati tí wọn ń gbé ìlú Eṣitemoa.

20. Simoni ni baba Aminoni, Rina, Benhanani ati Tiloni. Iṣi sì ni baba Soheti ati Benisoheti.

21. Ṣela, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Juda, ni baba Eri, baba Leka. Laada ni baba Mareṣa, ati ìdílé àwọn tí wọ́n ń hun aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun ní Beti Aṣibea

22. ati Jokimu, ati àwọn ará ìlú Koseba, Joaṣi ati Sarafu, tí wọ́n fi ìgbà kan jẹ́ alákòóso ní Moabu, tí wọ́n sì pada sí Bẹtilẹhẹmu. (Àkọsílẹ̀ yìí jẹ́ ti àtijọ́.)

23. Wọ́n jẹ́ amọ̀kòkò ní ààfin ọba, wọ́n sì ń gbé ìlú Netaimu ati Gedera.

24. Simeoni ni baba Nemueli, Jamini, Jaribu, Sera, ati Ṣaulu.

25. Ṣaulu bí Ṣalumu, Ṣalumu bí Mibisamu, Mibisamu sì bí Miṣima.

26. Àwọn ọmọ Miṣima nìyí: Hamueli, Sakuri, ati Ṣimei.

27. Ṣimei bí ọmọkunrin mẹrindinlogun ati ọmọbinrin mẹfa. Ṣugbọn àwọn arakunrin rẹ̀ kò bí ọmọ pupọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà rẹ̀ kò pọ̀ bí ẹ̀yà Juda.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 4