Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 29:11-14 BIBELI MIMỌ (BM)

11. OLUWA, o tóbi pupọ, tìrẹ ni agbára, ògo, ìṣẹ́gun, ati ọlá ńlá; nítorí tìrẹ ni ohun gbogbo ní ọ̀run ati ní ayé. Tìrẹ ni ìjọba, a gbé ọ ga bí orí fún ohun gbogbo.

12. Láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni ọrọ̀ ati ọlá ti ń wá, o sì ń jọba lórí ohun gbogbo. Ìkáwọ́ rẹ ni ipá ati agbára wà, ó wà ní ìkáwọ́ rẹ láti gbéni ga ati láti fún ni lágbára.

13. A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun wa, a sì yin orúkọ rẹ tí ó lógo.

14. “Ṣugbọn, kí ni mo jẹ́, kí sì ni àwọn eniyan mi jẹ́, tí a fi lè mú ọrẹ tí ó pọ̀ tó báyìí wá fún Ọlọrun tọkàntọkàn? Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, ninu ohun tí o fún wa ni a sì ti mú wá fún ọ.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 29