Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 25:9-17 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Gègé kinni tí wọ́n ṣẹ́ fún ìdílé Asafu mú Josẹfu; ekeji mú Gedalaya, òun ati àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin jẹ́ mejila.

10. Ẹkẹta mú Sakuri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

11. Ẹkẹrin mú Isiri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

12. Ẹkarun-un mú Netanaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

13. Ẹkẹfa mú Bukaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

14. Ekeje mú Jeṣarela, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

15. Ẹkẹjọ mú Jeṣaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

16. Ẹkẹsan-an mú Matanaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

17. Ẹkẹwaa mú Ṣimei, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 25