Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 24:16-31 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Petahaya, Jehesikeli,

17. Jakini, Gamuli;

18. Delaaya, Maasaya.

19. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n óo ṣe tẹ̀léra wọn níbi iṣẹ́ ṣíṣe ninu ilé OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Aaroni, baba wọn, ti là sílẹ̀ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun pa fún Israẹli.

20. Àwọn olórí ninu ìdílé àwọn ọmọ Lefi yòókù nìwọ̀nyí: Ṣubaeli láti inú ìdílé Amramu,Jedeaya láti inú ìdílé Ṣubaeli.

21. Iṣaya tí ó jẹ́ olórí láti inú ìdílé Rehabaya,

22. Ṣelomiti láti inú ìdílé Iṣari, Jahati láti inú ìdílé Ṣelomiti.

23. Àwọn ọmọ Heburoni jẹ́ mẹrin: Jeraya ni olórí wọn, bí àwọn yòókù wọn ṣe tẹ̀léra nìyí: Amaraya, Jahasieli ati Jekameamu.

24. Mika láti inú ìdílé Usieli, Ṣamiri láti inú ìdílé Mika.

25. Iṣaya ni arakunrin Mika. Sakaraya láti inú ìdílé Iṣaya.

26. Mahili ati Muṣi láti inú ìdílé Merari.

27. Àwọn ọmọ Merari láti inú ìdílé Jaasaya ni Beno ati Ṣohamu, Sakuri ati Ibiri.

28. Eleasari láti inú ìdílé Mahili, Eleasari kò bí ọmọkunrin kankan.

29. Jerameeli ọmọ Kiṣi, láti ìdílé Kiṣi.

30. Muṣi ní ọmọkunrin mẹta: Mahili, Ederi, ati Jerimotu. Àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ Lefi nìyí, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

31. Àwọn olórí ìdílé náà ṣẹ́ gègé gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Aaroni, àwọn arakunrin wọn ti ṣe, níwájú ọba Dafidi, ati Sadoku, ati Ahimeleki, pẹlu àwọn olórí ninu ìdílé alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 24