Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 22:18-19 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ó ní, “Ǹjẹ́ OLUWA Ọlọrun yín kò ha wà pẹlu yín? Ǹjẹ́ kò ti fun yín ní ìfọ̀kànbalẹ̀ káàkiri? Nítorí pé ó ti jẹ́ kí n ṣẹgun gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí, ilẹ̀ náà sì wà lábẹ́ àkóso OLUWA ati ti àwọn eniyan rẹ̀.

19. Nítorí náà, ẹ fi tọkàntọkàn wá OLUWA Ọlọrun yín nisinsinyii. Ẹ múra kí ẹ kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun, kí ẹ baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA ati gbogbo ohun èlò mímọ́ fún ìsìn Ọlọrun lọ sinu ilé tí ẹ óo kọ́ fún OLUWA.”

Ka pipe ipin Kronika Kinni 22