Nígbà tí àkókò òtútù kọjá, ní àkókò tí àwọn ọba máa ń lọ jagun, Joabu gbógun ti ilẹ̀ Amoni; wọ́n dó ti ìlú Raba. Ṣugbọn Dafidi dúró ní Jerusalẹmu. Joabu gbógun ti Raba, ó sì ṣẹgun rẹ̀.