Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 18:7-12 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Dafidi gba àwọn apata wúrà tí wọ́n wà lọ́wọ́ àwọn iranṣẹ Hadadeseri, ó kó wọn lọ sí Jerusalẹmu.

8. Ó kó ọpọlọpọ idẹ ní Tibihati ati Kuni, tí wọ́n wà lábẹ́ Hadadeseri. Idẹ yìí ni Solomoni fi ṣe agbada omi ńlá ati òpó ati àwọn ohun èlò idẹ fún ilé OLUWA.

9. Nígbà tí Toi, ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti ṣẹgun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, ọba Soba,

10. ó rán Hadoramu, ọmọ rẹ̀, pé kí ó lọ kí Dafidi ọba, kí ó sì bá a yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun tí ó ní lórí Hadadeseri, nítorí Hadadeseri ti bá Toi pàápàá jagun ní ọpọlọpọ ìgbà. Toi sì fi oríṣìíríṣìí ohun èlò wúrà, fadaka, ati idẹ ranṣẹ sí Dafidi.

11. Dafidi yà wọ́n sí mímọ́ fún OLUWA, fún iṣẹ́ ìsìn pẹlu àwọn fadaka ati wúrà tí ó gbà lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹgun: àwọn bíi Edomu ati Moabu, Amoni, Filistini ati Amaleki.

12. Abiṣai, ọmọ Seruaya, ṣẹgun àwọn ará Edomu ní àfonífojì Iyọ̀, ó pa ẹgbaa mẹsan-an (18,000) ninu wọn.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 18