Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 18:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà, Dafidi gbógun ti àwọn Filistini, ó ṣẹgun wọn, ó sì jagun gba ìlú Gati ati àwọn ìletò agbègbè rẹ̀ lọ́wọ́ wọn.

2. Dafidi ṣẹgun àwọn ará Moabu, wọ́n di iranṣẹ rẹ̀, wọ́n sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un.

3. Ó ṣẹgun Hadadeseri, ọba Siria ní Soba, ní agbègbè ilẹ̀ Hamati, bí Hadadeseri tí ń lọ fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ létí odò Yufurate.

4. Dafidi gba ẹgbẹrun (1,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ẹẹdẹgbaarin (7,000) ọmọ ogun ẹlẹ́ṣin, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ọmọ ogun lọ́wọ́ rẹ̀. Ó rọ́ àwọn ẹṣin náà lẹ́sẹ̀, ṣugbọn ó dá àwọn kan sí fún ọgọrun-un (100) kẹ̀kẹ́ ogun.

5. Nígbà tí àwọn ará Siria wá láti Damasku, láti ran Hadadeseri, ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi gbógun tì wọ́n, ó sì pa ẹgbaa mọkanla (22,000) ninu àwọn ọmọ ogun wọn.

6. Dafidi fi àwọn ọmọ ogun ṣọ́ Siria ti Damasku, àwọn ará Siria di iranṣẹ Dafidi, wọ́n sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ.

7. Dafidi gba àwọn apata wúrà tí wọ́n wà lọ́wọ́ àwọn iranṣẹ Hadadeseri, ó kó wọn lọ sí Jerusalẹmu.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 18