Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 17:18-27 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Kí ni mo tún lè sọ nípa iyì tí o bù fún èmi, iranṣẹ rẹ? Nítorí pé o mọ èmi iranṣẹ rẹ.

19. OLUWA, nítorí ti èmi iranṣẹ rẹ, ati gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni o fi ṣe àwọn nǹkan ńlá wọnyi, tí o sì fi wọ́n hàn.

20. Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, OLUWA, kò sì sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ti fi etí wa gbọ́.

21. Ní gbogbo ayé, orílẹ̀-èdè wo ni ó tún dàbí Israẹli, àwọn eniyan rẹ, tí ìwọ Ọlọrun rà pada láti jẹ́ eniyan rẹ, tí o sì sọ orúkọ rẹ̀ di ńlá nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí o ṣe nígbà tí ó lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn eniyan rẹ, tí o rà pada láti ilẹ̀ Ijipti?

22. O ti sọ àwọn eniyan rẹ, Israẹli, di tìrẹ títí lae, ìwọ OLUWA sì di Ọlọrun wọn.

23. “Nisinsinyii, OLUWA, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí o sọ nípa èmi iranṣẹ rẹ ṣẹ, ati ti ìran mi lẹ́yìn ọ̀la, kí o sì ṣe bí o ti wí.

24. Orúkọ rẹ yóo fìdí múlẹ̀ sí i, àwọn eniyan rẹ yóo sì máa gbé ọ́ ga títí lae, wọn yóo máa wí pé ‘OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí ó jẹ́ Ọlọrun Israẹli ni Israẹli mọ̀ ní Ọlọrun,’ ati pé ìdílé Dafidi, iranṣẹ rẹ, yóo fìdí múlẹ̀ sí i níwájú rẹ.

25. Nítorí pé ìwọ Ọlọrun mi, ti fi han èmi iranṣẹ rẹ pé o óo fìdí ìdílé mi múlẹ̀, nítorí náà ni mo ṣe ní ìgboyà láti gbadura sí ọ.

26. OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun, o ti ṣe ìlérí ohun rere yìí fún èmi iranṣẹ rẹ.

27. Nítorí náà, jẹ́ kí ó wù ọ́ láti bukun ìdílé èmi iranṣẹ rẹ, kí ìdílé mi lè wà níwájú rẹ títí lae, nítorí ẹnikẹ́ni tí o bá bukun, olúwarẹ̀ di ẹni ibukun títí lae.”

Ka pipe ipin Kronika Kinni 17