Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 16:6-20 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Bẹnaya ati Jahasieli, tí wọ́n jẹ́ alufaa, ni wọ́n ń fọn fèrè nígbà gbogbo níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun.

7. Ní ọjọ́ náà, àṣẹ àkọ́kọ́ tí Dafidi pa ni pé kí Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ máa kọ orin ìyìn sí OLUWA.

8. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA, ẹ képe orúkọ rẹ̀,ẹ kéde ohun tí ó ti ṣe fún àwọn orílẹ̀-èdè.

9. Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn sí i,ẹ sọ nípa àwọn ohun ìyanu tí ó ṣe!

10. Ẹ máa fi orúkọ rẹ̀ ṣògo,kí ọkàn àwọn tí wọn ń sin OLUWA kún fún ayọ̀.

11. OLUWA ni kí ẹ máa tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́,Ẹ máa sìn ín nígbà gbogbo.

12. Ẹ ranti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀,gbogbo nǹkan ìyanu tí ó ṣe, ati gbogbo ìdájọ́ rẹ̀,

13. ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀,ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.

14. Òun ni OLUWA Ọlọrun wa,ìdájọ́ rẹ̀ ká gbogbo ayé.

15. Kò ní í gbàgbé majẹmu rẹ̀ títí lae,àní àwọn ohun tí ó ti pa láṣẹ láti ṣe fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran,

16. majẹmu tí ó bá Abrahamu dá,ìlérí tí ó ti ṣe fún Isaaki,

17. tí ó sì ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹlu Jakọbu,gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ohun tí yóo wà títí lae,

18. ó ní, “Ẹ̀yin ni n óo fún ní ilẹ̀ Kenaani,bí ohun ìní yín, tí ẹ óo jogún.”

19. Nígbà tí wọn kò tíì pọ̀ pupọ,tí wọn kò sì jẹ́ nǹkan,tí wọ́n jẹ́ àjèjì níbẹ̀,

20. tí wọn ń lọ káàkiri láti orílẹ̀-èdè kan dé ekeji,láti ìjọba kan sí òmíràn,

Ka pipe ipin Kronika Kinni 16