Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 16:34-43 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA nítorí pé ó ṣeun,ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ sì wà títí lae!

35. Ẹ kígbe pé, “Gbà wá, Ọlọrun, olùgbàlà wa,kó wa jọ, sì gbà wá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,kí á lè máa dúpẹ́, kí á máa yin orúkọ mímọ́ rẹ,kí á sì máa ṣògo ninu ìyìn rẹ.

36. Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli,lae ati laelae!”Gbogbo àwọn eniyan sì dáhùn pe, “Amin”, wọ́n sì yin OLUWA.

37. Dafidi fi Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí iwájú Àpótí Majẹmu OLUWA láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀ lojoojumọ,

38. pẹlu Obedi Edomu ati àwọn arakunrin rẹ̀ mejidinlaadọrin; ó sì fi Obedi Edomu, ọmọ Jedutuni ati Hosa ṣe aṣọ́nà.

39. Ó fi Sadoku, alufaa ati àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ibi Àgọ́ OLUWA ní ibi pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní Gibeoni,

40. láti máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí pẹpẹ ẹbọ sísun, ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́, bí wọ́n ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli.

41. Hemani wà pẹlu wọn, ati Jedutuni ati àwọn mìíràn tí a yàn, tí a sì dárúkọ, láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

42. Hemani ati Jedutuni ní fèrè, aro, ati àwọn ohun èlò ìkọrin mìíràn tí wọ́n fi ń kọrin ìyìn. Àwọn ọmọ Jedutuni ni wọ́n yàn láti máa ṣọ́ àwọn ẹnu ọ̀nà.

43. Lẹ́yìn náà olukuluku pada sí ilé rẹ̀, Dafidi náà pada sí ilé rẹ̀ láti lọ súre fún àwọn ará ilé rẹ̀.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 16