Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 16:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Wọ́n gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun kalẹ̀ ninu àgọ́ tí Dafidi ti tọ́jú sílẹ̀ fún un, wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú Ọlọrun.

2. Nígbà tí Dafidi rú ẹbọ tán, ó súre fún àwọn eniyan ní orúkọ OLUWA,

3. ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, atọkunrin atobinrin, ní burẹdi kọ̀ọ̀kan, ati ègé ẹran yíyan kọ̀ọ̀kan ati àkàrà èso resini.

4. Ó sì yan àwọn ọmọ Lefi kan láti máa ṣe ètò ìsìn níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA: láti máa gbadura, láti máa dúpẹ́, ati láti máa yin OLUWA Ọlọrun Israẹli.

5. Asafu ni olórí, àwọn tí ipò wọn tún tẹ̀lé tirẹ̀ ni: Sakaraya, Jeieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Matitaya, Eliabu, Bẹnaya, Obedi Edomu ati Jeieli àwọn tí wọ́n ń ta hapu, tí wọ́n sì ń tẹ dùùrù. Asafu ni ó ń lu aro.

6. Bẹnaya ati Jahasieli, tí wọ́n jẹ́ alufaa, ni wọ́n ń fọn fèrè nígbà gbogbo níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun.

7. Ní ọjọ́ náà, àṣẹ àkọ́kọ́ tí Dafidi pa ni pé kí Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ máa kọ orin ìyìn sí OLUWA.

8. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA, ẹ képe orúkọ rẹ̀,ẹ kéde ohun tí ó ti ṣe fún àwọn orílẹ̀-èdè.

9. Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn sí i,ẹ sọ nípa àwọn ohun ìyanu tí ó ṣe!

10. Ẹ máa fi orúkọ rẹ̀ ṣògo,kí ọkàn àwọn tí wọn ń sin OLUWA kún fún ayọ̀.

11. OLUWA ni kí ẹ máa tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́,Ẹ máa sìn ín nígbà gbogbo.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 16