Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 15:21-26 BIBELI MIMỌ (BM)

21. ṣugbọn Matitaya, Elifelehu, Mikineiya, Obedi Edomu, Jeieli ati Asasaya ni wọ́n ń tẹ dùùrù.

22. Kenanaya ni a yàn láti máa darí orin àwọn ọmọ Lefi, nítorí pé ó ní ìmọ̀ orin.

23. Berekaya ati Elikana ni wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ibi tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu sí.

24. Àwọn alufaa tí wọ́n yàn láti máa fọn fèrè níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun ni: Ṣebanaya, Joṣafati, Netaneli, Amasa, Sakaraya, Bẹnaya, ati Elieseri. Obedi Edomu ati Jehaya pẹlu ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ibi tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu sí.

25. Dafidi ati àwọn àgbààgbà Israẹli ati àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun bá lọ sí ilé Obedi Edomu, wọ́n lọ gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ayọ̀.

26. Nítorí pé Ọlọrun ran àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu OLUWA lọ́wọ́, wọ́n fi mààlúù meje ati àgbò meje rúbọ.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 15