9. Àwọn ará Filistia ti dé sí àfonífojì Refaimu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti àwọn ìlú tí ó wà níbẹ̀, wọ́n sì ń kó wọn lẹ́rú.
10. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, ó ní: “Ṣé kí n lọ bá àwọn ará Filistia jà? Ṣé o óo jẹ́ kí n ṣẹgun wọn?”Ọlọrun dá a lóhùn pé, “Lọ bá wọn jà, n óo jẹ́ kí o ṣẹgun wọn.”
11. Dafidi bá lọ kọlù wọ́n ní Baali Perasimu, ó sì ṣẹgun wọn, ó ní, “Ọlọrun ti lò mí láti kọlu àwọn ọ̀tá mi bí ìkún omi.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Baali Perasimu.
12. Àwọn ará Filistia fi oriṣa wọn sílẹ̀ nígbà tí wọn ń sá lọ, Dafidi sì pàṣẹ pé kí wọ́n sun wọ́n níná.
13. Láìpẹ́, àwọn ará Filistia tún wá gbógun ti àwọn tí wọ́n wà ní àfonífojì, wọ́n sì kó wọn lẹ́rú.