Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 12:23-33 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Àwọn ìpín ọmọ ogun Dafidi tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní Heburoni, láti gbé ìjọba Saulu lé Dafidi lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA nìyí:

24. Láti inú ẹ̀yà Juda, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wá jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó dín igba (6,800) wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọ̀kọ̀.

25. Láti inú ẹ̀yà Simeoni, ẹẹdẹgbaarin ó lé ọgọrun-un (7,100), àwọn akọni jagunjagun ni wọ́n wá.

26. Láti inú ẹ̀yà Lefi, wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaata ó dín irinwo (4,600);

27. Jehoiada, olóyè, wá láti inú ìran Aaroni pẹlu ẹgbaaji ó dín ọọdunrun (3,700) ọmọ ogun

28. Sadoku ọdọmọkunrin akikanju jagunjagun wá, pẹlu ọ̀gágun mejilelogun ninu àwọn ará ilé baba rẹ̀.

29. Láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà kan náà pẹlu Saulu, àwọn tí wọ́n wá jẹ́ ẹẹdẹgbaaji (3,000). Tẹ́lẹ̀ rí, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí ìdílé Saulu.

30. Láti inú ẹ̀yà Efuraimu, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹrin (20,800) akikanju ati alágbára, tí wọ́n jẹ́ olókìkí ninu ìdílé wọn ni wọ́n wá.

31. Láti inú ìdajì ẹ̀yà Manase, ẹgbaasan-an (18,000) wá; yíyàn ni wọ́n yàn wọ́n láti lọ fi Dafidi jọba.

32. Láti inú ẹ̀yà Isakari, àwọn igba (200) olórí ni wọ́n wá, àwọn tí wọ́n mọ ohun tí ó bá ìgbà mu, ati ohun tí ó yẹ kí Israẹli ṣe; wọ́n wá pẹlu àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ wọn.

33. Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹgbaarun (50,000) àwọn ọmọ ogun, tí wọ́n gbóyà, tí wọ́n mọ̀ nípa ogun jíjà, tí wọ́n sì ní gbogbo ihamọra ogun ni wọ́n wá láti ran Dafidi lọ́wọ́ pẹlu ọkàn kan.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 12