Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 12:20-31 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Bí ó ti ń pada lọ sí Sikilagi, àwọn ará Manase kan wá, wọ́n bá darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi. Orúkọ wọn ni: Adina, Josabadi, Jediaeli, ati Mikaeli; Josabadi, Elihu ati Siletai, olórí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ ogun ninu ẹ̀yà Manase.

21. Wọ́n ran Dafidi lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn ìgárá ọlọ́ṣà kan, nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ akọni jagunjagun, wọ́n sì jẹ́ ọ̀gágun.

22. Lojoojumọ ni àwọn eniyan ń wá sọ́dọ̀ Dafidi láti ràn án lọ́wọ́; títí tí wọ́n fi pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n dàbí ogun ọ̀run.

23. Àwọn ìpín ọmọ ogun Dafidi tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní Heburoni, láti gbé ìjọba Saulu lé Dafidi lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA nìyí:

24. Láti inú ẹ̀yà Juda, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wá jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó dín igba (6,800) wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọ̀kọ̀.

25. Láti inú ẹ̀yà Simeoni, ẹẹdẹgbaarin ó lé ọgọrun-un (7,100), àwọn akọni jagunjagun ni wọ́n wá.

26. Láti inú ẹ̀yà Lefi, wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaata ó dín irinwo (4,600);

27. Jehoiada, olóyè, wá láti inú ìran Aaroni pẹlu ẹgbaaji ó dín ọọdunrun (3,700) ọmọ ogun

28. Sadoku ọdọmọkunrin akikanju jagunjagun wá, pẹlu ọ̀gágun mejilelogun ninu àwọn ará ilé baba rẹ̀.

29. Láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà kan náà pẹlu Saulu, àwọn tí wọ́n wá jẹ́ ẹẹdẹgbaaji (3,000). Tẹ́lẹ̀ rí, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí ìdílé Saulu.

30. Láti inú ẹ̀yà Efuraimu, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹrin (20,800) akikanju ati alágbára, tí wọ́n jẹ́ olókìkí ninu ìdílé wọn ni wọ́n wá.

31. Láti inú ìdajì ẹ̀yà Manase, ẹgbaasan-an (18,000) wá; yíyàn ni wọ́n yàn wọ́n láti lọ fi Dafidi jọba.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 12