Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 12:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ọkunrin wọnyi ni wọ́n lọ bá Dafidi ní Sikilagi, nígbà tí ó ń farapamọ́ fún Saulu, ọmọ Kiṣi; wọ́n wà lára àwọn akọni tí wọ́n ń ran Dafidi lọ́wọ́ lójú ogun.

2. Tafàtafà ni wọ́n, wọ́n sì lè fi ọwọ́ ọ̀tún ati ọwọ́ òsì ta ọfà tabi kí wọ́n fi fi kànnàkànnà. Ninu ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ti wá, wọ́n sì jẹ́ ìbátan Saulu.

3. Olórí wọn ni Ahieseri, lẹ́yìn náà, Joaṣi, ọmọ Ṣemaa; ará Gibea ni àwọn mejeeji. Lẹ́yìn wọn ni: Jesieli ati Peleti, àwọn ọmọ Asimafeti; Beraka, ati Jehu, ará Anatoti.

4. Iṣimaya, ará Gibeoni, akikanju jagunjagun ati ọ̀kan ninu “àwọn ọgbọ̀n” jagunjagun olókìkí ni, òun sì ni olórí wọn; Jeremaya, Jahasieli, Johanani ati Josabadi ará Gedera.

5. Elusai, Jerimotu, ati Bealaya; Ṣemaraya, Ṣefataya ará Harifi;

6. Elikana, Iṣaya, ati Asareli, Joeseri, ati Jaṣobeamu, láti inú ìdílé Kora,

7. Joela, ati Sebadaya, àwọn ọmọ Jehoramu, ará Gedori.

8. Àwọn ọkunrin tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Gadi láti darapọ̀ mọ́ Dafidi, ní ibi ààbò tí ó wà ninu aṣálẹ̀ nìwọ̀nyí; akọni ati ògbólógbòó jagunjagun ni wọ́n, wọ́n já fáfá ninu lílo apata ati ọ̀kọ̀, ojú wọn dàbí ti kinniun, ẹsẹ̀ wọn sì yá nílẹ̀ bíi ti ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín lórí òkè.

9. Orúkọ wọn, ati bí wọ́n ṣe tẹ̀léra nìyí: Eseri ni olórí wọn, lẹ́yìn náà ni Ọbadaya, Eliabu;

10. Miṣimana, Jeremaya,

Ka pipe ipin Kronika Kinni 12