Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 11:4-17 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Dafidi ati àwọn ọmọ Israẹli lọ gbógun ti ìlú Jerusalẹmu, (Jebusi ni orúkọ Jerusalẹmu nígbà náà, ibẹ̀ ni àwọn ará Jebusi ń gbé.)

5. Àwọn ará Jebusi sọ fún Dafidi pé, “O ò ní wọ ìlú yìí.” Ṣugbọn Dafidi ṣẹgun ibi ààbò Sioni, tí à ń pè ní ìlú Dafidi.

6. Dafidi ní, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ pa ará Jebusi kan ni yóo jẹ́ balogun fún àwọn ọmọ ogun mi.” Joabu, ọmọ Seruaya ni ó kọ́kọ́ lọ, ó sì di balogun.

7. Dafidi lọ ń gbé ibi ààbò náà, nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní ìlú Dafidi.

8. Ó tún ìlú náà kọ́ yípo, bẹ̀rẹ̀ láti Milo, ibi tí a ti kun ilẹ̀ náà yíká. Joabu sì parí èyí tí ó kù.

9. Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí di alágbára sí i, nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu rẹ̀.

10. Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí ninu àwọn akọni ọmọ ogun Dafidi nìwọ̀nyí; àwọn ni wọ́n fọwọsowọpọ pẹlu àwọn ọmọ Israẹli, láti fi Dafidi jọba, tí wọ́n sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí OLUWA ti ṣe fún Israẹli.

11. Àkọsílẹ̀ orúkọ wọn nìyí: Jaṣobeamu láti ìdílé Hakimoni ni olórí àwọn ọ̀gágun olókìkí mẹta. Òun ni ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọọdunrun (300) eniyan ninu ogun kan ṣoṣo.

12. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ninu àwọn ọ̀gágun olókìkí mẹta náà ni Eleasari ọmọ Dodo ará Aho.

13. Ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí Dafidi bá àwọn ará Filistia jagun ní Pasi Damimu, wọ́n wà ninu oko ọkà baali kan nígbà tí àwọn ọmọ ogun Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí sá fún àwọn ará Filistia.

14. Ṣugbọn òun ati àwọn eniyan rẹ̀ dúró gbọningbọnin ninu oko náà, wọ́n bá àwọn ará Filistia jà. OLUWA gbà wọ́n, ó sì fún wọn ní ìṣẹ́gun ńlá.

15. Ní ọjọ́ kan, mẹta ninu àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun olókìkí lọ sọ́dọ̀ Dafidi nígbà tí ó wà ní ihò Adulamu, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Filistini dó sí àfonífojì Refaimu.

16. Ibi ààbò ni Dafidi wà nígbà náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ogun Filistini sì ti wọ Bẹtilẹhẹmu,

17. Dafidi ranti ilé, ó ní, “Kì bá ti dùn tó kí n rí ẹni fún mi ní omi mu láti inú kànga tí ó wà lẹ́nu ibodè Bẹtilẹhẹmu!”

Ka pipe ipin Kronika Kinni 11