Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 11:12-26 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ninu àwọn ọ̀gágun olókìkí mẹta náà ni Eleasari ọmọ Dodo ará Aho.

13. Ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí Dafidi bá àwọn ará Filistia jagun ní Pasi Damimu, wọ́n wà ninu oko ọkà baali kan nígbà tí àwọn ọmọ ogun Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí sá fún àwọn ará Filistia.

14. Ṣugbọn òun ati àwọn eniyan rẹ̀ dúró gbọningbọnin ninu oko náà, wọ́n bá àwọn ará Filistia jà. OLUWA gbà wọ́n, ó sì fún wọn ní ìṣẹ́gun ńlá.

15. Ní ọjọ́ kan, mẹta ninu àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun olókìkí lọ sọ́dọ̀ Dafidi nígbà tí ó wà ní ihò Adulamu, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Filistini dó sí àfonífojì Refaimu.

16. Ibi ààbò ni Dafidi wà nígbà náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ogun Filistini sì ti wọ Bẹtilẹhẹmu,

17. Dafidi ranti ilé, ó ní, “Kì bá ti dùn tó kí n rí ẹni fún mi ní omi mu láti inú kànga tí ó wà lẹ́nu ibodè Bẹtilẹhẹmu!”

18. Àwọn akọni mẹta náà bá la àgọ́ àwọn ọmọ ogun Filistia já, dé ibi kànga náà, wọ́n sì bu omi náà wá fún Dafidi. Ṣugbọn ó kọ̀, kò mu ún; kàkà bẹ́ẹ̀, ó tú u sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún OLUWA.

19. Ó ní, “Kí á má rí i pé mo ṣe nǹkan yìí níwájú Ọlọrun mi. Ǹjẹ́ ó yẹ kí n mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkunrin wọnyi?” Nítorí pé ẹ̀mí wọn ni wọ́n fi wéwu kí wọn tó rí omi yìí bù wá; nítorí náà ni ó ṣe kọ̀, tí kò sì mu ún. Ó jẹ́ ohun ìgboyà tí àwọn akọni mẹta náà ṣe.

20. Abiṣai, arakunrin Joabu, ni olórí àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun. Ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọọdunrun eniyan, nípa bẹ́ẹ̀ òkìkí tirẹ̀ náà súnmọ́ ti àwọn akọni mẹta náà.

21. Òun ni ó lókìkí jùlọ ninu àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun náà, ó sì di olórí wọn; ṣugbọn kò ní òkìkí tó àwọn akọni mẹta.

22. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, láti ìlú Kabiseeli, jẹ́ ọmọ ogun tí ó ti ṣe ọpọlọpọ ohun ìyanu, ó pa àwọn abàmì eniyan meji ará Moabu. Ó wọ ihò lọ pa kinniun kan ní ọjọ́ kan tí yìnyín bo ilẹ̀.

23. Ó pa ará Ijipti kan tí ó ga ju mita meji lọ. Ará Ijipti náà gbé ọ̀kọ̀ tí ó tóbi lọ́wọ́. Ṣugbọn kùmọ̀ ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ lọ bá a, ó gba ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi pa á.

24. Àwọn ohun tí Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ṣe nìyí, tí ó sọ ọ́ di olókìkí, yàtọ̀ sí ti àwọn akọni mẹta tí a sọ nípa wọn.

25. Ó di olókìkí láàrin àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun; ṣugbọn òkìkí tirẹ̀ kò tó ti àwọn akọni mẹta náà. Dafidi bá fi ṣe olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba.

26. Àwọn olókìkí mìíràn ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi nìwọ̀nyí: Asaheli, arakunrin Joabu; ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu;

Ka pipe ipin Kronika Kinni 11