Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 11:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá parapọ̀, wọ́n wá sọ́dọ̀ Dafidi ní Heburoni, wọ́n ní, “Wò ó, ẹ̀jẹ̀ kan náà ni gbogbo wa pẹlu rẹ.

2. Látẹ̀yìnwá, nígbà tí Saulu pàápàá wà lórí oyè, ìwọ ni ò ń ṣáájú Israẹli lójú ogun. OLUWA Ọlọrun rẹ sì ti ṣèlérí fún ọ pé ìwọ ni o óo máa ṣe olùṣọ́ àwọn ọmọ Israẹli, eniyan òun, tí o óo sì jọba lé wọn lórí.”

3. Nítorí náà, àwọn àgbààgbà Israẹli wá sọ́dọ̀ Dafidi ọba, ní Heburoni. Dafidi sì bá wọn dá majẹmu níbẹ̀ níwájú OLUWA. Wọ́n fi òróró yàn án ní ọba lórí Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA láti ẹnu Samuẹli.

4. Dafidi ati àwọn ọmọ Israẹli lọ gbógun ti ìlú Jerusalẹmu, (Jebusi ni orúkọ Jerusalẹmu nígbà náà, ibẹ̀ ni àwọn ará Jebusi ń gbé.)

Ka pipe ipin Kronika Kinni 11