Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 10:6-14 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Bẹ́ẹ̀ ni Saulu, àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta ati àwọn ará ilé rẹ̀ ṣe kú papọ̀.

7. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé àfonífojì Jesireeli gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun ti sá lọ, ati pé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú, wọ́n sá kúrò ní ìlú wọn, àwọn ará Filistia wá wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.

8. Ní ọjọ́ keji, nígbà tí àwọn ará Filistia wá láti kó ìkógun, wọ́n rí òkú Saulu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta lórí Òkè Giliboa.

9. Wọ́n bọ́ ihamọra Saulu, wọ́n gé orí rẹ̀, wọ́n sì rán àwọn oníṣẹ́ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Filistini láti ròyìn ayọ̀ náà fún àwọn oriṣa wọn ati àwọn eniyan wọn.

10. Wọ́n kó àwọn ihamọra rẹ̀ sinu tẹmpili oriṣa wọn, wọ́n sì kan orí Saulu mọ́ ara ògiri tẹmpili Dagoni, oriṣa wọn.

11. Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi Gileadi gbọ́ bí àwọn ará Filistia ti ṣe Saulu,

12. gbogbo àwọn akọni ọkunrin tí wọ́n gbóyà gidigidi gbéra, wọ́n lọ gbé òkú Saulu ati òkú àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí Jabeṣi, wọ́n sì sin egungun wọn sí abẹ́ igi oaku ní Jabeṣi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ meje.

13. Bẹ́ẹ̀ ni Saulu ṣe kú nítorí aiṣododo rẹ̀; ó ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, ó sì lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ abókùúsọ̀rọ̀, ó lọ bèèrè ìtọ́sọ́nà níbẹ̀,

14. dípò kí ó bèèrè ìtọ́sọ́nà lọ́wọ́ OLUWA. Nítorí náà, OLUWA pa á, ó sì gbé ìjọba rẹ̀ fún Dafidi, ọmọ Jese.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 10