Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 1:45-54 BIBELI MIMỌ (BM)

45. Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu, ará ìlú kan ní agbègbè Temani, jọba tẹ̀lé e.

46. Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi, ọmọ Bedadi, tí ó ṣẹgun àwọn ará Midiani ní ilẹ̀ Moabu, jọba tẹ̀lé e. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.

47. Nígbà tí Hadadi kú, Samila ará Masireka, jọba tẹ̀lé e.

48. Nígbà tí Samila kú, Ṣaulu ará Rehoboti létí odò Yufurate, jọba tẹ̀lé e.

49. Nígbà tí Ṣaulu kú, Baali Hanani, ọmọ Akibori, jọba tẹ̀lé e.

50. Nígbà tí Baali Hanani kú, Hadadi, jọba tẹ̀lé e. Ìlú tirẹ̀ ni Pau. Iyawo rẹ̀ ni Mehetabeli, ọmọ Matiredi, ìyá rẹ̀ àgbà ni Mesahabu. Nígbà tí ó yá, Hadadi náà kú.

51. Àwọn ìjòyè ẹ̀yà Edomu nìwọ̀nyí: Timna, Alia, ati Jeteti;

52. Oholibama, Ela, ati Pinoni,

53. Kenasi, Temani, ati Mibisari,

54. Magidieli ati Iramu.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 1