Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 1:35-46 BIBELI MIMỌ (BM)

35. Àwọn ọmọ Esau ni Elifasi, Reueli, ati Jeuṣi; Jalamu ati Kora.

36. Àwọn ọmọ Elifasi ni Temani, Omari ati Sefi; Gatamu, Kenasi, Timna ati Amaleki.

37. Àwọn ọmọ Reueli ni Nahati, Sera, Ṣama ati Misa.

38. Àwọn ọmọ Seiri ni Lotani, Ṣobali ati Sibeoni; Ana, Diṣoni, Eseri ati Diṣani.

39. Àwọn ọmọ Lotani ni Hori ati Homami. Lotani ní arabinrin kan tí ń jẹ́ Timna.

40. Àwọn ọmọ Ṣobali ni Aliani, Manahati ati Ebali; Ṣefi ati Onamu. Sibeoni ni baba Aia ati Ana.

41. Ana ni baba Diṣoni. Àwọn ọmọ Diṣoni ni Hamirani, Eṣibani, Itirani ati Kerani.

42. Eseri ló bí Bilihani, Saafani ati Jaakani. Diṣani ni baba Usi ati Arani.

43. Àwọn ọba tí wọ́n jẹ ní ilẹ̀ Edomu, kí ọba kankan tó jẹ ní ilẹ̀ Israẹli nìwọ̀nyí: Bela, ọmọ Beori; orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.

44. Nígbà tí Bela kú, Jobabu, ọmọ Sera, ará Bosara, jọba tẹ̀lé e.

45. Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu, ará ìlú kan ní agbègbè Temani, jọba tẹ̀lé e.

46. Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi, ọmọ Bedadi, tí ó ṣẹgun àwọn ará Midiani ní ilẹ̀ Moabu, jọba tẹ̀lé e. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 1